Leviticus 4:13-21

13 a“ ‘Bí gbogbo àpapọ̀ ènìyàn Israẹli bá ṣèèṣì ṣẹ̀, tí wọ́n sì ṣe ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe sí ọ̀kan nínú àwọn òfin Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpapọ̀ ènìyàn náà kò mọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n jẹ̀bi. 14Nígbà tí wọ́n bá mọ̀, gbogbo ìjọ ènìyàn yóò mú akọ màlúù wá sí àgọ́ ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 15Kí àwọn àgbàgbà ìjọ Israẹli gbé ọwọ́ lórí akọ ọmọ màlúù náà níwájú Olúwa. 16Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn sì mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ akọ ọmọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé. 17Kí ó ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọn ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa níbi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà. 18Kí ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé. Ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó dà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 19Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá kúrò lára rẹ̀, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ. 20Kí ó sì ṣe akọ ọmọ màlúù yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ṣe ètùtù fún wọn, á ó sì dáríjì wọ́n. 21Lẹ́yìn náà ni yóò sun màlúù yìí lẹ́yìn ibùdó, yóò sì sun ún gẹ́gẹ́ bó ṣe sun màlúù àkọ́kọ́. Èyí ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli.

Copyright information for YorBMYO